2 Kings 23:4-20

4 aỌba sì pàṣẹ fún Hilkiah olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lé e ní ipò àti àwọn olùṣọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Baali àti Aṣerah àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jerusalẹmu ní pápá Àfonífojì Kidironi. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Beteli. 5Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Juda láti sun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Juda àti àwọn tí ó yí Jerusalẹmu ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Baali, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn ààmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. 6Ó mú ère òrìṣà Aṣerah láti ilé Olúwa sí Àfonífojì Kidironi ní ìta Jerusalẹmu, ó sì sun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí àtíkè ó sì fọ́n eruku náà sórí isà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀. 7Ó sì wó ibùgbé àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún òrìṣà Aṣerah.

8Josiah kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Juda ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Geba sí Beerṣeba, níbi tí àwọn àlùfáà ti sun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti Joṣua, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá. 9Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jerusalẹmu, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn.

10Ó sì ba ohun mímọ́ Tofeti jẹ́, tí ó wà ní Àfonífojì Beni-Hinnomu, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Moleki. 11Ó sì kúrò láti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa, àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà. Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Natani-Meleki. Josiah sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn.

12Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Juda ti wọ́n gbé dúró ní orí òrùlé lẹ́bàá yàrá òkè ti Ahasi pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Manase ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé Olúwa. Ó ṣí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Ó sì da ekuru wọn sínú Àfonífojì Kidironi. 13Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Jerusalẹmu ní ìhà gúúsù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Aṣtoreti ọlọ́run ìríra àwọn ará Sidoni, fún Kemoṣi ọlọ́run ìríra àwọn ará Moabu àti fún Moleki, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ammoni. 14Josiah fọ́ òkúta yíyà sọ́tọ̀, ó sì gé ère Aṣerah lulẹ̀. Ó sì bo ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pẹ̀lú egungun ènìyàn.

15Àní pẹpẹ tí ó wà ní Beteli ibi gíga tí Jeroboamu ọmọ Nebati dá. Tí ó ti fa Israẹli láti ṣẹ̀—Àní pẹpẹ náà àti ibi gíga tí ó fọ́ túútúú. Ó jó àwọn ibi gíga, ó sì lọ̀ ọ́ sí ẹ̀tù, ó sì sun ère Aṣerah pẹ̀lú. 16Nígbà náà, Josiah wò yíká, nígbà tí ó sì rí àwọn isà òkú tí ó wà níbẹ̀ ní ẹ̀bá òkè, ó yọ egungun kúrò lára wọn, ó sì jó wọn lórí pẹpẹ láti sọ ọ́ di èérí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí a ti kéde láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀.

17Ọba sì béèrè pé “Kí ni ọwọ́n isà òkú yẹn tí mo rí?”

Àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wí pé, “Ó sàmì sí isà òkú ènìyàn Ọlọ́run tí ó wá láti Juda, tí ó sì kéde ìdojúkọ pẹpẹ Beteli, ohun kan wọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe sí wọn.”

18“Fi sílẹ̀ nìkan,” Ó wí pé. “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó da àwọn egungun rẹ̀ láàmú.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá egungun rẹ̀ sí àti ti àwọn wòlíì tí ó wá láti Samaria.

19Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Beteli, Josiah sì kúrò, ó sì ba gbogbo ojúbọ òrìṣà ti ibi gíga jẹ́, tí àwọn ọba Israẹli ti kọ́ sí àwọn ìlú ní Samaria, tí ó ti mú Olúwa bínú. 20Josiah dúńbú gbogbo àwọn àlùfáà ibi gíga lórí pẹpẹ. Ó sì sun egungun ènìyàn lórí wọn. Nígbà náà, ó padà lọ sí Jerusalẹmu.

Copyright information for YorBMYO